Ilé àkójójọpọ̀ àlùmọ́nì ìgbanì tí ó ti ṣe agbátẹrù ìṣìfihàn tí ó báyémú tí o sì jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, tí ó ní ṣe pẹlú ìtàn, ìṣe, àti ọjọ ìwájú Yorùbá ni yóò ṣe agbátẹrù ètò Gbọ̀ngàn John Randle. Èyí ni rí gbọ́ láti ẹnu àwọn ẹgbẹ́ alámójútó tí wọn ti pinnu láti ṣe àfihàn Ẹwà Àṣà wa. 

Èyí tí yóò máa ṣe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún èyí, niìṣàfihàn olóṣù mẹ́fàmẹ́fà, tí ó jẹ́ pé àkọ́lé oríṣìíríṣìí ni ó máa dá lé. Ìṣẹ́lẹ̀ -lọ́wọ́lọ́wọ́ – ìse ojú-ọjọ́, ìdánilẹ́kọ̀ọ́, àkọ́sórí, ìbáraẹnisọ̀rọ̀, tàbí ohun mìíràn – máa ri dájú pé ibi-iṣẹ́ náà jẹ́ ibi pàtàkì sí ìṣàfihàn àṣà Yorùbá àti sí àṣà Nàìjíríà. 

Bí ìṣàfihàn yìí ti wà ní téńté ìparí ní ìdàgbàsókè, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe ìwádìí díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́-ọnà wa tí a ti tò sí ìpín yìí, ní èyí tí yóò jẹ́ kí ẹ mọ díẹ̀ nípa ohun tí ó ń bọ̀ lọ́nà.

All images © Ademola Olaniran & Jide Atobatele

Àwọn Ibi Ìṣàfihàn

Àwọn Ìtàn Ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ dúró gẹ́gẹ́ bí ìṣíde fún àwọn àlejò sí ọkan pàtàkì nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìhà tí àṣà àti ìtàn Yorùbá ní: ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀. Ibí tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì ní igbá aláwẹ́-méjì, èyí tí ó dúró fún ọ̀run àti ayé. Ohún oríkì tí ó ń lọ ní abẹ́lẹ̀, èyí tí ó ń ṣe àpèjúwé ohun tí ó ń lọ lọ́wọ́ nínú ayé, ń mú ẹ̀rù bani, ẹ̀rù náà sì ń pọ̀ síi bí ohun oríkì náà ṣe ń tẹ̀síwájú pẹlù ohun dídún àti àrá. Aṣọ ìtàgé bo àyíká, èyí tí ó ń pe àkíyèsí sí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín òfo kí ayé tó bẹ̀rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ inú ayé, ìrìnkiri àti ohùn tí ó tẹ̀lé e lẹ́yìn tí ayé bẹ̀rẹ̀.

Ilẹ́ ti orí, tàbí ilé orí, ni ó ṣídé ìtàn, ojúbọ òrìṣà mẹ́rìndílógún ni ó yíi ká, èyí tí ó túnmọ̀ sí àkójọ alálẹ̀ Yorùbá, èyíkéyìí nínú àwọn àlejò yóò si dá èyí mọ̀. Ẹ̀kúnrẹ́ré ìtúnmọ̀ pàtó tí ó ń ṣàlàyé bí ilé orí ṣe dúró fún àjọṣepọ̀ tí ó wà láàárín ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan àti orí inú rẹ̀, bákan náà ni èyí ṣe àlàyé ipa tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òrìṣà ń kó nínú àṣà Yorùbá. Àlàyé tún wà lórí - Ìtùmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí àṣẹ ní – èyí tí Olódùmarè fún ohun ẹ̀da tí ó dá.

Ìṣẹ̀se àti ìṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun àkọ́kọ́ tí ènìyàn kò gbọ̀dọ má, èyí tí ẹ̀nikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọmọ ìran Yorùbá máa là kọjá:  sísọ ọmọ tuntun ní orúkọ (ìsọmọlórúkọ). Àjọṣepọ̀ ìgbàlódé a lo díjíìtì gba àwọn àlejò ní ìyànjú láti fi orúkọ Yorùbá wọn sílẹ̀ láti rih ìtunmọ̀ àti pàtàkì orúkọ wọn, nígbàtí ògiri tí wọn ya èrè ìbejì sí múnilójú, tí ó sì yànàná àjọyọ ìbísíi fún àwọn àlejò. 

Lẹ́yìn orúkọ sísọ, ohun tí ó tẹ̀lé e ni ìtàn àṣẹ àṣírí/ìkọ̀kọ̀ – ìṣe àwọn ọba àti àwọn afọbajẹ -ojú tí a fi wo èyí ni àwọn nǹkan pàtàkì tí ó ṣe àfihàn ìdarí ààfin ̀ti ọba, èyí tí o jẹ mọ gbogbo ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá.  Ibi Ọjà ṣe àfihàn ìdàkeji àṣẹ ìkọ̀kọ̀, ó ṣàlàyé ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ aṣọ, oúnjẹ àti ìpele tí ó wà nínú ọjà Yorùbá. Èyí fi kún ìdáyàtọ̀ gbogbo àwọn ìlú Yorùbá, ilẹ̀ sí orí òrùlé máa ṣe àfihàn ọdún egúngún káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, àti àwọn ẹ̀kú/àgọ̀ egúngún láti oríṣiríṣi ọdún egúngún ilẹ̀ Yorùbá gẹ́gẹ́ bí ìṣàfihàn onírúurú. 

Ìbẹ̀rẹ̀ ìmúnisìn ní ṣẹ́ńtúrí kọkàndínlógún, àti òwò ẹrú tí ó tẹ̀ lé e, ni o fi ojú àwọn nǹkan bíi ìgbà ìmúnisiìn wò- ìgò, bíbélì, mànílà àti èròjà ogun. Ohun tí yóò mú ènìyàn lójú ni ìlẹ̀kùn tí wọ́n gbẹ́ tí ó sì ń sọ ìtàn àwọn òyìnbó àti iṣẹ́ wọn ní ìlú Èkó. Nínú iṣẹ́-ọnà tí ó wà lárà ìlẹ̀kún yìí, àwọn nǹkan tí ó ní ṣe pẹ̀lú Yorùbá òde òní fi ara hàn díẹ, bíi àjọṣepò tí ó wà láàárín ìmúnisìn-tipátipá àti ìtàn àwọn Yorùbá tí wọ́n wà ní ilẹ̀ òkèrè. 

àwọn àlejò máa kọ́ pé àṣà Yorùbá ti yátọ̀, ó sì ti dí ti òde òní ní Nàìjíríà lẹ́yìn-òmìnira. Nínú eré títà tí ó ń ṣe àfihàn ìlú ńlá tí ó mú oríṣìíríṣìí nǹkan tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìlú Èkó wá sí ọkan, a rí àfihàn àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ àwọn akọni Yorùbá, láti inú orin, òṣèlú àti lítíréṣọ̀, láti ara àwọn ìse Yorùbá tí ó fún wọn ní ìmísí láti ṣẹ̀dá wọn. Awọn orin Fẹlà, King Sunny Adé àti àwọn olórin Yorùbá mìíràn tí àwọn àlejò ngbọ́, fún wọn ni àǹfààní láti wo ìyàtọ̀ àti ìjọra ìlu Yorùbá àti orin, bakan náà ní wọ́n ṣe àtúpalẹ̀ àwọn iṣẹ́ ọnà aláwòmọ lítitíréṣọ̀ tí ó yanrantí, láti ara ìtàn orírun àti ìṣẹ̀dálẹ̀. Oríṣìíríṣìí àwọn àrà aṣọ, bẹ̀rè láti orí lúrẹ́ẹ̀si dé orí léèsì ni wọ́n fi sọ ìtàn oge ṣíṣe ìgbàlódé, bákan náà sì ní wọn fi ààye kan sílẹ̀ tí wọ́n fi jin igbó Ọ̀ṣun-Òṣogbo, àti ìtàn tí o rọ̀ mọ́ ìrìn ̀jò bí ó ṣe di ohun ìpatì títí dí bí ó ṣe dí ohun àtúnṣe.

Yorùbá Ọjọ́ Ọ̀la

Lópin ìrìn àjò àlejò ni ààyè Ọjọ́ Iwájú Yorùbá, ààyè fún ìṣàfihàn ọjọ́ ránpẹ́ tí yóò gba àwọn iṣẹ́ ọnà tó wá láti ọwọ́ àwọn oníṣẹ́ ọnà Èkó àti àwọn oníṣẹ́ ọnà tó wá láti òkè òkun. Àwọn oníṣẹ́ ọnà yìí ni wọn ó máa dáhùn sí àwọn ìbéèrè àti àkọlé tí a pè jáde láti inú àròkọ tí Wálé Lawal kọ tí a ń pè ní Àìmàsìkò, tí ó ro ọjọ́ iwájú Yorùbá láti àfojúsùn orí oníidẹ Ifẹ̀ kan tó sọnù. Jọ̀wọ́ tẹ̀ láti ka Ìsọléréfèé Àìmàsìkò.

Ìgbékalẹ̀ Ibi Ìṣàfihàn Títíláí

‘Ohun ti o wa leyin offa, o ju oje lo.’

‘What follows six is more than seven.’


‘Àṣà wa jẹ́ àṣà òde òní.’


Gbọ̀ngàn John Randle Centre jẹ́ ilé ìkóoun mèremère ọnà sí (mùsíọ́mù) kìnní irù ẹ̀ nílẹ̀ Africa. A kọ́ọ láti fún ẹ, ìwọ àlejò, ní ìran sínú àṣà àti àwùjọ àwọn ènìyàn tí wọ́n pe ara wọn ní Yorùbá, bóyá ní Nàìjíríyà tàbí káàkiri àgbàyé. Gbọ̀ngàn náà dìde jáde láti inú àǹfàní láti tún ilẹ̀ olókìkí ilé JK Randle, tí Randle tó jẹ́ dókítà olówó olókìkí ọmọ Yorùbá fúnra rẹ̀ ṣí. Ìgbà tí a bẹ̀rẹ̀, èyí jẹ́ kí Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó mú àbá wá láti sọ Onikan di àárín gbùngbùn gbọ̀ngàn àṣà l’Ékòó. Kà Síi…