Wòyíká

Gbọ̀ngàn John Randle jẹ́ irú ilé ìkóun mèremère ọnà sí (mùsíọ́mù) àrà ọ̀tọ̀. A lo ọ̀nà àti kó oun àtijọ́ jọ tí a máa ń lò nílùú òyìnbó láti ṣẹ̀dá ọ̀nà ìsọ̀tàn tuntun mìíràn tí àṣà Yorùbá gbé lárugẹ. Ó gbé àwọn àṣà tí a lè fọwọ́kàn àti àwọn tí a ò lè fọwọ́kàn lárugẹ, ó sì ń ṣe ìpamọ́, ìpolongo, àti ìgbélárugẹ ogún ìní àṣà àwọn ọmọ Yorùbá.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, Gbọ̀ngàn yìí ń ṣe àkójopọ̀ àwọn iṣẹ́ ọnà tí ó pẹ̀ka tí ó pọ̀, tí yóò mú kí ó yàtò gbáà sí ibi ìsàfihàn àkójọpọ̀ ohun ìgbàanì àbáláyé. National Commission for Museums and Monuments pẹ̀lú National Museum tí ó wà ní ìlú Èkó ń ran gbọ̀ngàn yìí lọ́wọ́ láti kó àwọn nǹkan jọ pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn a-gba-nǹkan-ìṣura-jọ ọlọdanni. Gbọ̀ngàn John Randle ṣe agbátẹrù rírí dájú pé àwọn ìṣúra ìgbàanì ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n ti kó lọ Yuróòpu di dídápada sí ilé a ní àjọṣepọ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú British Museum, Pitt Rivers Museum àti University ti Leeds ní UK. 

Ní tí ìmọ ìjìnlẹ̀, àwọn ìṣàfihàn ibi-iṣẹ́ yìí ni ó jẹ wípẹ àwọn iṣẹ-ọnà Rowland Abiodun ni o bí wọn, ní pàápàá, ìwé rẹ̀ tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Yoruba Art and Language: Seeking the African in African Art, tí ilé ìtẹ̀wétà Cambridge University Press gbe jáde ní ọdún 2014.